Baale ile mẹjọ ti wọn fẹẹ f'ori oku ṣoogun owo l'Ọṣun ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 7, 2022

Baale ile mẹjọ ti wọn fẹẹ f'ori oku ṣoogun owo l'Ọṣun ti ha o


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ awọn baale ile mẹjọ kan, lori ẹsun wi pe wọn ba ori oku lọwọ wọn, eyi ti wọn n gbero lati fi ṣoogun owo.
 
Ilu Iwo to wa n'ipinlẹ naa la gbọ pe ọwọ ti tẹ gbogbo wọn.
 
Ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Afọlabi Jacob ni iroyin fi to wa leti wi pe ọwọ awọn fijilante ẹlẹsin musulumi kan ti wọn pe ni Taawun Security, Al-Jayshu Islam kọkọ tẹ pẹlu ori oku naa, iyẹn l'Ọjọru, Wẹside ana.
 
Agbegbe Yemọja to wa niluu Iwo la gbọ pe ọwọ ti tẹ Afọlabi, nibẹ lo si ti jẹwọ wi pe ṣe loun fẹẹ ta ori oku naa f'awọn ọrẹ oun ti wọn fẹẹ fi ṣe etutu aje.

Ninu atẹjade ti olori fijilante naa, Jamaatu Taawunil Muslimeen fi sita ni wọn ti sọ pe Afọlabi lo ṣe atọna bi ọwọ ṣe tẹ awọn meje yooku ti wọn mọ nipa ori oku naa.
 
Loju ẹsẹ ti ọwọ ti tẹ gbogbo wọn la gbọ pe wọn ti lọ fa wọn le ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun lọwọ lati tẹsiwaju iwadii lori wọn.
 
Yẹmisi Ọpalọla to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ninu ọrọ tirẹ sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori awọn afurasi ọdaran naa, to si jẹ ko di mimọ pe wọn ko ni pẹ ẹ f'oju ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI