Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede sita wi pe awọn n wa baale ile, ẹni ọdun mejilelogoji kan, Ibukun Oluṣọla Ọlajide, to dagbere ibi ayẹyẹ igbeyawo kan niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ti ko si pada sile mọ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee ọsẹ to kọja ni wọn so pe Ọlajide jade kuro nile ẹ to wa niluu Ado-Ekiti, to si loun n lọ sibi ayẹyẹ igbeyawo kan nuu iluu Ibadan.
Latigba naa ni wọn ti sọ pe Ọlajide ko pada sile, eyi to ko awọn ẹ sinu ironu.
Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Sunday Abutu to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa fi sita, o jẹ ka mọ pe adugbo Oho-Oluwa, Asungbowoọla, oju ọna Afao niluu Ado-Ekiti lọkunrin naa n gbe, ati pe nnkan bi agogo mẹrin irọlẹ lo jade kuro nile.
O sọ pe ninu iwadii ti awọn ṣe ni wọn ti mọ pe Ọlajide ko de ilu Ibadan, depodepo wi pe yoo de ibi ayẹyẹ igbeyawo to dagbere.
Gbogbo akitiyan awọn ẹbi rẹ lati mọ ibi to wa lo ja si pabo, idi to fi l'awọn n kede wi pe ẹnikẹni to ba ti ba wọn kofiri rẹ, ki wọn fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, tabi ki wọn pe nọmba ẹrọ ibanisọrọ 09064050086.
No comments:
Post a Comment