Ẹ wo oju Samuel to fun ọmọ ọga rẹ l’oyun l’Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 1, 2022

Ẹ wo oju Samuel to fun ọmọ ọga rẹ l’oyun l’Ekoo


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ ọmọ ogun ọdun kan, Samuel Maikasuw ti wọn lo f’ipa ja ibale ọmọ ọga rẹ, ọmọ ọdun mẹẹdogun, to si tun fun un l’oyun.

 
Agbegbe Ikorodu la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ti waye laipẹ yii.

Ohun ti a gbọ ni pe iṣẹ ọlọdẹ ni wọn gba Samuel fun, wi pe ko ma a ba wọn ṣi geeti ile, ṣugbọn ti wọn pada sọ pe ko lọ maa ba wọn ta ọja ni ṣọọbu ọga rẹ.

Wọn ni ọdun to kọja ni wọn ṣakiyesi wi pe Samuel fẹ maa ba ọmọ naa laṣepọ, eyi to jẹ ki wọn tete gbe e kuro nile, ti wọn si ni ko lọ maa ṣiṣẹ ni ṣọọbu.

Ko s’ẹni to le sọ bo tun ṣe lọ ki ọmọ naa mọlẹ, to si n ba a laṣepọ, titi to fi l’oyun.

Awọn obi ọmọ ọhun lo ṣakiyesi wi pe ara rẹ ko ya, ti wọn si lọ ṣe ayẹwo fun un, nibi ti aṣiri ti tu wi pe oyun lo wa lara rẹ.

Eyi lo jẹ ki wọn lọ fi ẹjọ sun awọn fijilante agbegbe Ikorodu, ti wọn si lọ mu, ko to di pe wọn lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori isẹlẹ ọhun, to si l’awọn yoo ṣe ohun to tọ labẹ ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI