Ẹ wo oju ọmọ Kwara to di giwa fasiti West Scotland ni UK - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 1, 2022

Ẹ wo oju ọmọ Kwara to di giwa fasiti West Scotland ni UK


Ṣe ni inu gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara bẹrẹ si i dun ṣinṣin, nigba ti fasiti kan nilẹ United Kingdom, iyẹn University of West Scotland sọ Arabinrin Yekẹmi Ọtaru (née Awoseyin) di giwa agba wọn.
 
Ọmọ bibi ipinlẹ Kwara ni wọn pe Arabinrin Yekẹmi, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
B'awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara, paapaa awọn ololufẹ obinrin naa kaakiri agbaye ṣe n ba a ṣajọyọ naa ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ naa n sọ pe idunnu nla lo jẹ f'ọun wi pe oriire nla bẹẹ wọle tọ oun wa.
 
Ọkan lara awọn ọmọ Ọmọwe Raphael Sunday Awosẹyin lati ilu Ayedun, ijọba ibilẹ Oke-Ero nipinlẹ Kwara ni wọn pe Arabinrin Ọtaru, ẹni ti wọn lo ti gbe iṣẹ ironilagbara rẹ kaakiri agbaye, lati fi ṣaanu f'awọn eeyan.
 
Nigba to n sọrọ, Gomina AbdulRazaq sọ pe
“A fi idunnu wa han si Arabinrin Yekẹmi Ọtaru ati mọlẹbi rẹ, paapaa gbogbo ilu Oke Ero lapapọ lori itan tuntun ti wọn fi balẹ yii. Ohun iwuri lo jẹ fun wa wi pe ọmọ ipinlẹ lo tun fi itan tuntun balẹ, ti gbogbo agbaye si n ba a yọ fun aṣeyọri rẹ, paapaa fun ti ifarajin rẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI