EXODUS: Awọn oloye ati alẹnulọrọ PDP Kwara ko ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ẹgbẹ lọ APC, wọn l'awọn gbọdọ ṣatilẹyin fun ipadabọ AbdulRazaq lẹẹkeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 13, 2022

EXODUS: Awọn oloye ati alẹnulọrọ PDP Kwara ko ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ẹgbẹ lọ APC, wọn l'awọn gbọdọ ṣatilẹyin fun ipadabọ AbdulRazaq lẹẹkeji'Ẹni to ba mọ ọna ni ki ẹ jẹ ka tẹle, awa n ba AbdulRazaq lọ', wọnyi lorin ti awọn oloye ati alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Kwara n kọ nigba ti wọn n darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.
 
Wọn ni ki i ṣe pe awọn n darapọ mọ  ẹgbẹ oṣelu APC nikan, bi ko ṣe pe awọn fẹẹ ṣatilẹyin fun ipadabọ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lẹẹkeji, nitori pe iṣakoso rẹ n tẹ wọn lọrun.

Nibẹ ni wọn tun ti n tẹnumọ ọn wi pe awọn ko le maa tẹle iṣakoso to n faaye gba iwa jagidijagan, ẹgbẹ okunkun ati tọọgi mọ n'ipinlẹ naa, bi ko ṣe pe awọn yoo tubọ maa tẹle iṣakoso to fẹran alaafia ati igbayegbadun araalu, nitori ọjọ iwaju wọn.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI