Afi ka gbaruku ti ipadabọ AdbulRazaq lẹẹkeji - Ẹmir ilu Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 13, 2022

Afi ka gbaruku ti ipadabọ AdbulRazaq lẹẹkeji - Ẹmir ilu IlọrinẸmir tilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari ti sọ ọ di mimọ pe Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq yẹ lẹni ti wọn n fun ni tikẹẹti lẹẹkeji, nitori pe iṣakoso rẹ ko waye n'ipinlẹ naa, to si ti jẹ k'awọn mọ pe ojulowo ọmọ-ọkọ ni.
 
Ọmọwe Sulu-Gambari lo sọrọ naa l'ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii niluu Ilọrin nibi ayẹyẹ ọlọdọọdun 'Bareke' ti wọn ṣe kọja.
 
Nibẹ ni Ẹmir naa ti sọ pe Gomina AbdulRazaq ti fi ara jin pupọ fun igbayegbadun araalu, to si ni ọrọ araalu jẹ ẹ logun gidi.
 
"Mo ti ri i daadaa wi pe ọlọlajulọ n ṣiṣẹ gidi, o si tun ti ṣetan lati tubọ ṣe ju awọn eyi to n ṣe tẹlẹ lọ. O ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Erongba mi ati adura mi ni pe ki o wọle saa keji lati tubọ ṣe aṣeyọri si i" - Ẹmir.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI