Idibo Ọṣun: Oyetọla ni yoo jawe olubori, alawada lasan ni Adeleke - Wolii Ayọdele - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 11, 2022

Idibo Ọṣun: Oyetọla ni yoo jawe olubori, alawada lasan ni Adeleke - Wolii Ayọdele


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual to wa niluu Eko, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ti sọ pe awọn oludije s'ipin gomina labẹ asia ẹgbẹ alatako kan n fi akoko wọn ṣofo danu lasan naa, nitori pe Gomina Isiaka Adegboyega Oyetọla ni yoo pada wọle lati ṣe saa keji.
 
Wolii Ayọdele lo sọ eyi di mimọ ninu asọtẹlẹ tuntun to ṣẹṣẹ gbe jade l'opin ọsẹ to kọja yii, iyẹn nibi ikojade iwe asọtẹlẹ ọlọdọọdun nni to pe ni 'Warnings To The Nations'.
 
Nibẹ lo tun ti jẹ ko di mimọ pe ko si oludije lati ẹgbẹ oṣelu alatako n'ipinlẹ Ogun to le bori ẹni ti iṣakoso wa lọwọ lasiko yii, Ọmọọba Dapọ Abiọdun.
 
O ni bo tilẹ jẹ pe oludije s'ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ni agbara ati owo, sibẹ, ko le bori Oyetọla ninu idibo to n bọ lọna yii.

Ninu ọrọ rẹ, A ni
Oyetọla maa bori Michael Jackson ninu eto idibo to n bọ lọna yii, alawada lasan ni Ademọla jẹ, ko le bori Oyetọla.

Bakan naa lo tun sọ pe
Bo tilẹ jẹ pe Gomina Dapọ Abiọdun ko ṣe daadaa n'ipinlẹ Ogun, sibẹ, o maa bori, nitori pe ko si alatako to lagbara lati koju e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI