Biliọnu mẹrin naira ni ijọba fi n san owo oṣu, ati owo ifẹhinti l'oṣooṣu - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 10, 2022

Biliọnu mẹrin naira ni ijọba fi n san owo oṣu, ati owo ifẹhinti l'oṣooṣu - AbdulRazaq


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe owo ti ko din ni biliọnu mẹrin naira l'awọn fi n san owo oṣu awọn oṣiṣẹ ati iwo ifẹhinti awon oṣiṣẹfẹhinti l'oṣooṣu.

AbdulRazaq lo sọ eyi di mimọ l'Ọjọbọ, Tọside to kọja yii niluu Ilọrin, nibi to ti jẹ ounjẹ aṣalẹ pẹlu awọn ti Ẹmir ilu Ilọrin, Alaaji Ibrahim Sulu-Gambari ṣẹṣẹ fi joye

Gomina naa ti oludamọran pataki rẹ, Alaaji Saadu Salahu ṣoju fun, nigba to n sọrọ sọ pe awọn eto ati ilana iṣakoso yii ni lati jẹ ki awọn araalu wa ni igbayegbadun.

O wa pe awọn ọmọ ati olugbe ilu Ilọrin lati ṣamulo ilana idagbasoke ti ijọba ipinlẹ naa ṣẹṣẹ gbe kalẹ lati fi mu ilọsiwaju ba ilu naa.

Awọn oloye tuntun naa ni: Ọmọwe Alimi AbdulRazaq (Mutawali), Malaamu Salihu Mustapha (Turaki), Alaaji Saka Onimago (Shettima), Alaaji Yakubu Gobir (Madawaki), Sheikh Sulaiman Onikijipa (Mufti), Sheikh Imam Yakub Aliagan (Seriki Malami) ati Onimọ-ẹrọ Kale Kawu (Dan Iya).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI