Ijọba ipinlẹ Ogun bu ọwọ lu yiyan Ọba Olowu, Onitele at'awọn ọba tuntun miran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 27, 2022

Ijọba ipinlẹ Ogun bu ọwọ lu yiyan Ọba Olowu, Onitele at'awọn ọba tuntun miran


Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun ti kede sita wi pe ohun ti bu ọwọ lu awọn ọba tuntun l'awọn ijọba ibilẹ to wa n'ipinlẹ naa.
 
Lara awọn ọba tuntun ti ijọba bu ọwọ lu lati jẹ ni Olowu tilu Owu Abẹokuta, Onitele tilu Itele, Aboro tilu Ibeṣe, Lẹmọ tilu Ode Lẹmọ, at'awọn miran.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin fi sita lonii, Ọjọru, Wẹside, o ni ijọba ipinlẹ Ogun bu ọwọ lu awọn ọba tuntun naa latari ipade ti Gomina Dapọ Abiọdun ṣe pẹlu awọn ọba alaye l'ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Nibẹ lo tun ti jẹ ko di mimọ pe ijọba ipinlẹ Ogun tun ti bu ọwọ lu awọn oloye tuntun mọkanla ọtọọtọ, to si ni ki igbesẹ bẹrẹ lori yiyan wọn si ipo to tọ.
 
Ṣomọrin, sọ pe lara awọn ti ijọba bu ọwọ lu ni ipo Onikooko tilu Kooko Ebiye, ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta; Olu tilu Ajura, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi-Owode.
 
O tẹsiwaju pe awọn ti yoo di awọn ipo ọhun mu ni Ọmọọba Saka Adelọla Matẹmilọla, ti yoo di Olowu tilu Owu n'ijọba ibilẹ Abẹokuta North; Ọmọọba Oluwaṣeyi Rotimi Mulero ti yoo di Aboro tilu Ibeṣe n'ijọba ibilẹ Yewa North, nigba ti Ọmọọba Rufai Adeleke Adeyalu yoo di Lẹmọ tilu Ode-Lẹmọ, ijọba ibilẹ Ṣagamu.

Awọn miran ni Ọmọọba Ademọla Eletu ti yoo di Onitele tilu Itele, ijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta; Ọmọọba Ogunṣọla Muyideen Oluṣeyi Soile ti yoo di Ayanperuwa tilu Ṣotubọ, ijọba ibilẹ Ṣagamu; Ọmọọba Lukman Salami, Ebi tilu Idena n'ijọba ibilẹ Ikẹnnẹ.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe wọn ti yi ipo Oniboro tilu Iboro pada si Aboro t'ilu Iboro, ijọba ibilẹ Yewa North.
 
O wa kadi rẹ nilẹ pe igbimọ naa tun bu ọwọ lu Oloye Rasheed Adisa Raji gẹgẹ bi Aṣipa ilu Ẹgba ati Oloye Ganiu Kọlawọle Egunjọbi gẹgẹ bi Ọtun ilu Ẹgba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI