Opin de ba ẹgbẹ oṣelu APC to d'ori eto ọrọ aje Naijiria kodo - Aderinokun pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 27, 2022

Opin de ba ẹgbẹ oṣelu APC to d'ori eto ọrọ aje Naijiria kodo - Aderinokun pariwo sita


Oludije s'ipo aṣofin agba orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, Oloye Olumide Aderinokun ti sọ pe ki gbogbo ọmọ orileede yii dide lati fi opin si iṣakoso ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lori bo ṣe sọ pe wọn ti dori eto ọrọ aje Naijiria kodo.
 
Aderinokun, ẹni to tun jẹ Akinruyiwa t'ilu Owu, Abẹokuta lo sọ eyi di mimọ niluu Abẹokuta lakoko to n b'awọn akọroyin sọrọ, bu ẹnu atẹ lu ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari.

O ni gbogbo nnkan lẹka eto ijọba lo ti dorikodo patapata, eyi to sọ pe ko ba oju mu to, paapaa julọ, bo ṣe sọ pe eto aabo orileede yii ti dẹnukọlẹ patapata.

Siwaju si i lo sọ pe ipo ti eto ọrọ epo rọbii wa ko bojumu to, ati pe b'awọn agbebọn ṣe kọlu ilu Abuja to jẹ olu-ilu Naijiria laipẹ jẹ ohun to n kọ oun lominu.

Aderinokun sọ pe ibanujẹ nla lo jẹ wi pe iṣakoso ẹgbẹ oṣelu APC ti n wa ọkọ orileede yii lọ si ebute iparun, to si ni ẹlẹdaa gbogbo awọn olotitọ lorileede yii yoo ṣe idajọ fun wọn.
 
Nigba to n gb'awọn eeyan lamọran, o ni ki onikaluku lọ maa gbaradi fun eto idibo ọdun 2023 lati le ẹgbẹ APC danu, ko to di pe wọn wọn dori Naijiria kodo patapata.
 
Bakan naa lo tun f'ẹsun kan ijọba APC wi pe wọn ti ya owo to kọja agbara Naijiria, ti ko si si idagbasoke kankan lẹka eto ọrọ aje.

N'igba to n mẹnuba iwọde ifẹhonu han t'ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kaakiri orileede yii n ṣe lori b'awọn akẹkọọ fasiti kaakiri Naijiria ṣe wa nile lati oṣu keji ọdun yii, o ni ohun to ṣe pataki julọ ni ki ijọba apapọ tete da ẹgbẹ ASUU lohun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI