Kwara bu ọwọ lu owo oṣu tuntun f'awọn oṣiṣẹ ile-ẹkọ giga, bẹẹ ni wọn tun san owo oṣu ajẹẹlẹ awọn oṣiṣẹ Kwara Express - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 26, 2022

Kwara bu ọwọ lu owo oṣu tuntun f'awọn oṣiṣẹ ile-ẹkọ giga, bẹẹ ni wọn tun san owo oṣu ajẹẹlẹ awọn oṣiṣẹ Kwara Express


Idunnu nla lo ṣubu lu ayo awọn oṣiṣẹ ile-ẹkọ giga kaakiri ipinlẹ Kwara, pẹlu bi gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq ṣe bu ọwọ lu owo oṣu tuntun fun wọn.
 
Ọjọ Aje, Mọnde ana la gbọ pe ijọba ati ileeṣẹ kan ti wọn pe ni Joint Public Service Negotiating Council tọwọ bọwe adehun lori sisan owo oṣu tuntun, ẹgbẹrun lọna ọgbọn f'awọn oṣiṣẹ.
 
Lara awọn il-ẹkọ giga ti ọrọ yii kan ni Colleges of Education, Kwara State Polytechnic ati College of Arabic and Islamic Legal Studies (CAILS).

Wọn ni bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun 2022 ni wọn bẹrẹ si i san owo oṣu tuntun naa, ati sisan gbogbo owo oṣu ajẹẹlẹ, to fi mọ awọn ẹtọ to ti wa nilẹ.

Nigba to n sọrọ, olori awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa, Modupẹ Oluwọle sọ pe ipele to kẹyin ninu eto sisan owo oṣu tuntun fáwọn oṣiṣẹ ijọba l'awọn bu ọwọ lu naa, eyi ti yoo tun jẹ ki wọn ṣe agbeyẹwo owo oṣu tuntun naa.
 
O jẹ ko di mimọ pe ọjọ karundinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2022 l'awọn tọwọ bọ iwe adehun pẹlu ileeṣẹ Joint Public Service Negotiation Council (JNC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, nitori awọn ẹgbẹ bi i Senior Staff Union in Colleges of Education Nigeria (SSUCOEN) ati Non-Academic Staff Union (NASU), ni ibamu pẹlu Consolidated Tertiary Education Institutions Salary Structure (CONTEDISS).

Siwaju si i lo sọ pe "gbogbo eeyan lo mọ bi nnkan ṣe ri lorileede yii lonii. Ọpọ awọn ipinlẹ lo le koko fun lati san owo oṣu tuntun f'awọn oṣiṣẹ, eyi ti Kwara naa wa lara wọn, Ṣugbọn ọlọlajulọ wa, Malamu AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣe sisan owo oṣu ni ohun akọkọ lakoko to yẹ. Gomina si ti ṣe ileri wipe ko si nnkan ti yoo yẹ adehun naa."

Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Kwara, Kọmureedi Isa Ore ninu ọrọ tiẹ, gbe oriyin fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori bo ṣe n mu awọn ileri rẹ ṣẹ loore-koore.
 
Lara awọn to tun wa nibi titọwọbọ iwe adehun naa ni alaga Public Service Joint Negotiating Council,Kọmureedi Saliu Suleiman; Alakoso Establishment, Pension and Industrial Relations, Alaaji Yusuf Amuda; Akọwe ẹgbẹ Public Service Joint Negotiating Council, Kọmureedi Joseph Tunde; Akọwe agba nileeṣẹ eto idajọ, Alaaji Musa Idris; Akọwe agba nileeṣẹ Establishment and Training, Alaaji Ibrahim Mohammed; Alaga ẹgbẹ NASU, Kọmureedi Adebayọ Gegele; ati Alakoso, iyẹn State Controller of Labour Federal Ministry of Labour and Employment, Alaaji Yusuf Raufu.

Iroyin miran to tun fi ara pẹ eyi ni bi Gomina AbdulRazaq tun ṣe bu ọwọ lu sisan owo oṣu ajẹẹlẹ f'awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Harmony Transport Services Limited (Kwara Express) tẹlẹri.

A gbọ pe gbogbo erongba Gomina AbdulRazaq ni lati ma ṣe jẹ oṣiṣẹ yoowu lowo, iyẹn latigba to wa n'ijọba lọjọ kọkandinlọgbọ, oṣu karun-un, ọdun 2019, ti a si gbọ pe gbogbo owo t'awọn iṣakoso to kọja lọ ti jẹ silẹ lo fẹẹ san patapata.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI