Ẹ lọ gba kaadi idibo alalopẹ yin o- Dapọ Abiọdun sọ f'awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 26, 2022

Ẹ lọ gba kaadi idibo alalopẹ yin o- Dapọ Abiọdun sọ f'awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ogun


Bi idibo ọdun, 2023 ṣe n sunmọ etile, Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti kede sita wi pe oun ti ya oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee silẹ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ naa lati jade lọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn ki asiko to o lọ.
 
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2022 ni ajọ eleto idibo lorileede Naijiria, iyẹn INEC sọ pe eto iforukọsilẹ gbigba kaadi idibo alalopẹ yoo dopin.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Kunle Ṣomọrin fi sita l'ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii lo ti sọ pe ko ni i si iṣẹ l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee oni fun anfaani awọn ti wọn ko ti i gba kaadi idibo alalopẹ wọn.

Bakan naa lo sọ pe eyi yoo fun gbogbo awọn ti wọn ti sọ kaadi idibo alalopẹ wọn nu, ati awọn ti wọn fẹẹ ṣe atunṣe lori ibudo idibo tuntun tabi oniruuru atunṣe to ba yẹ ni wọn yoo lanfaani lati ṣe e.

Abiọdun wa gba gbogbo eeyan lamọran lati ri i pe wọn kopa ninu eto idibo apapọ to n bọ l'ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI