Nítorí oriṣiriṣi ẹsun iwa ọdaran, Headies le 'Portable' danu ninu awọn akopa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 26, 2022

Nítorí oriṣiriṣi ẹsun iwa ọdaran, Headies le 'Portable' danu ninu awọn akopa


Ileeṣẹ kan to n fun awọn gbajugbaja olorin ni aami ẹyẹ lọdọọdun lati fi gbe oriyin ati oṣuba kare fún iṣẹ wọn, iyẹn Headies ti kede sita wi pe gbajugbaja olorin takasufe nni, Habeeb Okikiọla ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Portable ko ni i lanfaani lati kopa nibi eto ọhun fun ti ọdun.

Ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin ni Headies mu Portable mọ awọn olorin to gbajumọ daadaa lọdun 2022 ti a wa yii, ti wọn si ni yoo figagbaga pẹlu awọn ti wọn jọ ṣe daadaa ni ipele ti wọn ka a mọ.

Ipele 'Best Street Artist' ati 'Rookie of the Year' ni wọn ka ọmọkunrin to kọ orin Zazu naa mọ.

Nigba ti wọn n kede idi ti wọn fi yọ orukọ rẹ kuro ninu awọn akopa, Headies ni oriṣiriṣi awọn iwa ọdaran ni wọn ti fi kan an, bẹẹ si ni ko mọ bi wọn ṣe n ko ara ẹni ni ijanu.

Wọn ni Portable ti figba kan ri sọ pe oun yoo pa ẹni ti wọn ba gbe awọọdu ipele ti wọn ka oun si fun, bẹẹ si loun yoo digun lọ b ẹnikẹni to ba fee figagbaga.

Yatọ si eyi, wọn ni Portable tun sọ laipẹ yii pe oun ni olori awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun 'One Million Boys', ati Ajah Boys ti wọn da wahala nla silẹ lakoko iwọde EndSars.

Wọn tun sọ pe Portable nita gbangba ko àwọn ọmọ ẹyin rẹ lati lu DJ Chicken nilukulu, ko da to tun sọ pe ki wọn pa a.

Wọn ni awọn ẹsun yii ko ba ilana ofin bi wọn ṣe n fun awọn olorin ni aami ẹyẹ mu, eyi ti wọn fi sọ pe Portable ko le lanfaani lati kopa mọ.

Ẹkunrẹrẹ iwe ti wọn fi sita ree:


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI