Ibi-a-ba-'ṣẹ-de: Towoju bẹrẹ eto ojukoju pẹlu awọn araalu ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 26, 2022

Ibi-a-ba-'ṣẹ-de: Towoju bẹrẹ eto ojukoju pẹlu awọn araalu ni Kwara


Lojuna lati gbọ erongba awọn araalu lori ibi ti iṣẹ akanṣe ku si, Kọmiṣanna f'ọrọ eto iroyin nipinlẹ Kwara, Ọnarebu Ọlabọde George Towoju ti bẹrẹ akanṣe eto ojukoju pẹlu awọn araalu.

Ọjọ Ẹti, Furaidee ọsẹ to kọja yii ni akọkọ iru eto bẹẹ ti wọn pe ni 'Face-to-Face with Towoju', iyẹn ni pe Ojukoju pẹlu Towoju bẹrẹ, ti awọn eeyan si n gbe oṣuba kare.

Eto ọhun gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ ni yoo fun awọn araalu lanfaani lati tubọ sọ ohun ti wọn n fẹ ki ijọba ṣe fun wọn, yala lori awọn iṣẹ akanṣe to n lọ kaakiri, tabi nnkan miran.

Ori ikanni amohunmaworan ti ipinlẹ naa, iyẹn Tẹlifiṣan Kwara ni eto ọhun yoo ti maa waye ni gbogbo Ọjọru, Wẹside, laaarin agogo mẹta si mẹta aabọ ọsan.

Nibẹ ni wọn yoo ti maa gba alejo awọn eeyan ni oriṣiriṣi ẹka, eyi ti yoo fun awọn araalu lanfaani lati pe wọle sọ ohun ti wọn ba fẹẹ sọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI