O ma ṣe o! L'ọjọ ọdun Ileya, gbajugbaja sọrọsọrọ nni, Abiọdun Ọrọpọ jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 10, 2022

O ma ṣe o! L'ọjọ ọdun Ileya, gbajugbaja sọrọsọrọ nni, Abiọdun Ọrọpọ jade laye


Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ti f'idi rẹ mulẹ pe ọkan lara awọn agba sọrọsọrọ to fi ilu Eko ṣe ibugbe, Abiọdun Ọrọpọ ti jade laye.

Abiọdun Ọrọpọ ti wọn tun n pe ni Oyinlọmọ Alaaji la gbọ pe o jade laye lalẹ ọjọ ọdun Ileya to waye ni ana, ọjọ Abamẹta, Satide.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i gbọ nipa kulẹkulẹ iru iku to pa gbajugbaja sọrọsọrọ ori redio ati telifisan naa, sibẹ a gbọ pe bi ere, bi awada lọrọ ri nigba to maa jade laye.

A gbọ oe ọkunrin naa ṣe ayẹyẹ nla nile ẹ, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ si wa ba a ṣayẹyẹ ọdun naa, koda to tun ba wọn dapara gẹgẹ bi iṣẹ rẹ.

Ọrọpọ lakoko ayẹyẹ ọdun Ileya to ṣe lanaa

Irọ ni, ko le ri bẹẹ, ko le jẹ otitọ lọrọ kayeefi to n jade lẹnu awọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye, ṣugbọn ti aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ.

Oni, ọjọ Aiku, Sannde la gbọ pe wọn yoo sin ọkunrin naa ni ilana musulumi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI