Ọwọ tẹ Ọpẹyẹmi ati Adetunji to ji ẹran Ileya gbe l'Ogijo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 7, 2022

Ọwọ tẹ Ọpẹyẹmi ati Adetunji to ji ẹran Ileya gbe l'Ogijo


Iya ko to lilu f'awọn ọkunrin meji ti ẹ n wo yii lagbegbe Ogijo, nigba tọwọ palaba wọn segi nibi ti wọn ti lọ ji ẹran Ileya ti wọn so mọlẹ gbe.
 
Nnkan bi agogo mẹta oru Ọjọru, Wẹside to kọja yii la gbọ pe Adetunji Alagbe, Ọpẹyẹmi Ogunlokun ati ẹnikẹta wọn toun ti na papa bora lọ ji ẹran naa to jẹ ti ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Sọdiq Abọlọrẹ gbe.
 
Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ṣe ṣalaye f'awọn akọroyin niluu Abẹokuta, o ni Abọlọrẹ lo kẹẹfin awọn eeyan naa nibi ti wọn ti n gbe ẹran rẹ sinu mọto wọn, to si pariwo le wọn lori.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Oju oorun ni Abọlọrẹ wa to ti n gburo ẹsẹ lẹyinkule rẹ, eyi lo jẹ ko yọju loju ferese, to si ṣakiyesi pe ẹran agbo to fẹẹ fi ṣe ọdun Ileya ko si nibi to so o si, ati pe ilẹkun to fi dina ibi to so ẹran naa mọ, wọn ti gbe e kuro.

"Loju ẹsẹ lo ti sare dide ni nnkan bi agogo mẹta oru lati lọ wo nnkan to n ṣẹlẹ. Bo ṣe jade sita lo ri awọn mẹta ti wọn n fipa gbe ẹran agbo naa sinu mọto ti wọn gbe wa. Nibẹ lo ti pariwo sita, ti awọn eeyan si jade lati le wọn mu.

"Ọkan lara wọn raaye na papa bora. B'ọwọ sẹ tẹ wọn, ni wọn ti lọ fa wọn le awọn ọlọpaa Ogijo lọwọ. Ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira ni Abọlọrẹ loun ra ẹran agbo naa ti wọn fẹẹ jigbe."
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti wa paṣẹ wi pe ki wọn tubọ ṣe iwadii awọn mejeeji yii daadaa, ko to di pe wọn fi oju wọn ba ile-ẹjọ.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI