Tọpẹ ati Musibau ha nibi aṣekagba ipolongo idibo l'Oṣogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 13, 2022

Tọpẹ ati Musibau ha nibi aṣekagba ipolongo idibo l'Oṣogbo


Lonii, Ọjọru, Wẹsidee ni ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun sọ pe awọn yoo fa awọn afurasi ọdaran meji t'ọwọ tẹ nibi ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu APC n'ipinlẹ Ọṣun to kọja yii le awọn ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju iwadii wọn.
 
Awọn mejeeji naa, Tọpẹ Jaiye ati Musibau Isiaka lọwọ palaba wọn segi nibi ti wọn ti n ji owo ati dukia lapo awọn eeyan nibi aṣekagba ipolongo idibo ọhun to waye ni papa iṣere Oṣogbo City.
 
Jaiye ninu ọrọ rẹ sọ pe ilu AKurẹ, n'ipinlẹ Ondo loun ti wa, nigba ti Isiaka ni tiẹ sọ pe ilu Ibadan n'ipinlẹ Ọyọ loun naa ti wa.
 
Nigba to n fi irioyin ọhun lede, Amitolu Shittu to jẹ alakoso ileeṣẹ Amọtẹkun n'ipinlẹ Ọṣun sọ pe awọn mejeeji ti jẹwọ pe ki i ṣe akọkọ ree t'awọn yoo maa jale, ati pe awọn ko le ka iye ole ti wọn ti ja.
 
O ni foonu ati owo ni wọn jigbe ki ọwọ to o tẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI