Aderinokun, ẹni to tun jẹ Akinruyiwa tilu Owu Abẹokuta sọ pe ko si awijare kankan ninu iroyin ẹlẹjẹ ti ẹgbẹ APC n gbe kaakiri ori ayelujara wi pe wọn ti oun mọ ọgba ẹwọn kirikiri.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Aderinokun, Ọgbẹni Taye Taiwo gbe jade lonii, Ọjọbọ, Tọside, o ni iroyin ọhun ko l'ẹsẹ nilẹ rara nitori pe irọ to jinna si otitọ patapata ni.
O ni ko si otitọ kankan ninu iroyin wi pe wọn fi ẹsun jibiti kan Aderinokun, ti wọn si dajọ fun un pe ki wọn lọ tii mọ ọgba ẹwọn kirikiri, bi ko ṣe pe ẹgbẹ oṣelu APC kan fẹẹ fi ba a lorukọ jẹ lasan ni.
Aderinokun ṣapejuwe iroyin ọhun gẹgẹ bi ipinnu igbesẹ to ti di oku.
Ninu atẹjade naa, o ni lotitọ ni Aderinokun ni aawọ kekere kan laarin ileeṣẹ rẹ ati ijọba ipinlẹ Eko, ti aawọ naa si de ile ẹjọ.
"Ọdun 2017 ni ijọba ipinlẹ Eko gbe Oloye Aderinokun lọ sile ẹjọ giga ipinlẹ Eko lori ọrọ ti ko to nnkan. Ninu ẹjọ naa, ile ẹjọ paṣẹ pe ki wọn gba beeli Aderinokun pẹlu awọn gbedeke kan.
"Loju ẹsẹ ni awọn oniduro ti dide lati duro fun un, ti ko si f'ẹsẹ tẹ Kirikiri gẹgẹ bi wọn ṣe n gbe kaakiri.
"Lẹyin ọpọlọpọ igbẹjọ, ile ẹjọ da ẹsun naa ni ni ibamu pẹlu abala 71 ti ACJI 2021."
O wa sọ pe iroyin ẹlẹjẹ naa ko lee ko irẹwẹsi ba Oloye Aderinokun ati awọn ara agbegbe aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nitori pe àwọn araalu mọ otitọ
Bakan naa lo ni Aderinokun ko nii dawọ duro lati maa fi ẹrin si ẹrẹkẹ awọn ara ijọba ibilẹ mẹfẹẹfa to wa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment