AbdulRazaq bura fun Kọmiṣanna tuntun mẹrin ati amugbalẹgbẹẹ pataki kan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 3, 2022

AbdulRazaq bura fun Kọmiṣanna tuntun mẹrin ati amugbalẹgbẹẹ pataki kan


Lanaa ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq bura fun Kọmiṣanna mẹrin ọtọọtọ ati amugbalẹgbẹẹ pataki kan lati le jẹ ki ijọba rẹ ṣe aṣeyọri to lọọrin.

Awọn Kọmiṣanna ati amugbalẹgbẹẹ pataki yii ni gomina ti fi orukọ wọn ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin lati ṣe agbeyẹwo wọn boya wọn yoo kun oju oṣuwọn.

Lẹyin ọpọlọpọ iwadii ati ayẹwo, ni igbimọ ọhun fi ontẹ lu wọn gẹgẹ bii pe wọn peregede.

Nibi ipade igbimọ iṣakoso ipinlẹ naa, eyi ti gomina dari rẹ ni AbdulRazaq ti bura fun wọn lapapọ.

Awọn naa ni Alaaji Agbaje Wahab (Whyte) ti wọn gbe lọ si ileeṣẹ to n ri sọrọ omi, iyẹn Ministry of Water Resources; Ibrahim Akaje ti yoo ṣakoso okoowo, idagbasoke tuntun ati imọ ẹrọ igbalode, iyẹn Business, Innovation and Technology; Adenikẹ Harriet Oshatimẹhin ti wọn gbe lọ si ẹka to n ri sọrọ ohun alumọni ti wọn n pe ni Solid Minerals; Ọmọwe Afeez Abọlọrẹ ti yoo bojuto ile ẹka giga, iyẹn Tertiary Education; ati Lateef Alakawa Gidado toun naa yoo bojuto iṣẹ agbẹ ati ọgbin (Agric).

Nibẹ naa ni gomina tun ti ṣe atunto igbimọ iṣakoso rẹ, to si ṣe iṣipopada awọn Kọmiṣanna.

Architect Aliyu Mohammed Saifudeen to wa ni ileeṣẹ ijọba ibilẹ ni wọn gbe lọ si ileeṣẹ idagbasoke igberiko (Local Government to Housing and Urban Development); Aliyu Kora Sabi to wa ni ileeṣẹ ina (Energy) ni wọn gbe lọ si ileeṣẹ akanṣe iṣẹ (Special Duties).

Bakan naa ni gomina tun bura fun Atiku Abdusalam gẹgẹ bi oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ Civic Engagement. 

O wa gba gbogbo wọn lamọran lati ṣiṣẹ wọn fun idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ naa.





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI