Ẹ wo ojú àwọn kọmíṣánnà tuntun méje tí Dàpọ Abíọ́dún búra fún l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 24, 2022

Ẹ wo ojú àwọn kọmíṣánnà tuntun méje tí Dàpọ Abíọ́dún búra fún l'Ógùn


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti bura fawọn kọmiṣanna tuntun ti ko din ni meje ati igbakeji olori awọn oṣiṣẹ gomina kan, lojuna lati le jẹ ki iṣẹ idagbasoke ipinlẹ naa kẹsẹjare.

Oludọtun Taiwo (Forestry); Ganiyu Hamzat (Local Government and Chieftaincy Affairs); Arabinrin Motunrayọ Adelẹyẹ -Ọladapọ (Culture and Tourism); Ọgbẹni Ọladimeji Ọrẹsanya (Environment); Arabinrin Olufẹmi Ilọri Ọduntan (Special Duties and Inter -Governmental Affairs); Ọnarebu Abayọmi Hunye (Community Development and Cooperatives) ati Ọgbẹni Jamiu Ọdẹtoogun (Rural Development).

Kọmiṣanna tẹlẹ f'ọrọ eto aṣa ati igbafẹ, Ọmọwe Toyin Taiwo ti di igbakeji olori awọn oṣiṣẹ gomina bayii.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana ni Gomina Dapọ Abiọdun bura fawọn eeyan naa ni ọfiisi rẹ to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta, nibẹ lo si ti gba wọn lamọran lati duro ṣinṣin ninu iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI