Ẹgbẹ agbabọọlu ogun fẹẹ figagbaga lori ife-ẹyẹ Aderinokun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 25, 2022

Ẹgbẹ agbabọọlu ogun fẹẹ figagbaga lori ife-ẹyẹ Aderinokun


Ẹgbẹ agbabọọlu ti ko din ni ogun la gbọ pe wọn ti n gbaradi lati figagbaga ninu idije Aderinokun Unity Cup to fẹẹ waye n'ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ Ogun.

A gbọ pe ajọ alaanu Olumide and Stephanie Aderinokun lo fẹẹ ṣagbatẹru idije naa to fẹẹ bẹrẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹjọ ti a wa yii.

Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ wa lọwọ lati ọwọ akọwe iroyin Oloye Aderinokun, Taye Taiwo, o ni lara ironilagbara ti ajọ naa n ṣe fawọn ọdọ ni idije ọhun jẹ. 


Taiwo ni idije naa ti wọn pe akori rẹ ni "2022 Workers Unity Cup", ni wọn gbe kalẹ lẹyin ti idije ti "Aderinokun Charity Cup" to waye n'ijọba ibilẹ Ifọ ati Ewekoro kẹsẹjare.

Nigba ti wọn n to awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo kopa papọ, alakoso ajọ naa, Ọgbẹni Abiọdun Ogunrẹmi sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu ogun ni yoo koju ara wọn ninu idije naa.

O jẹ ko di mimọ pe awọn ẹgbẹ ni yoo bii ẹgbẹ oni burẹdi, agbẹ, telọ, kunle-kunle, ati bẹẹbẹẹlọ ni wọn fẹẹ figagbaga, ti wọn yoo si mu ipo kin-ni-in, ipo keji ati ipo kẹta laaarin wọn.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI