Ọrọ pesijẹ! Awọn ọba Kwara f'ohun ṣọkan, wọn ni 'Gomina AbdulRazaq at'awọn adije lẹgbẹ APC la maa dibo fun l'ọdun 2023' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 25, 2022

Ọrọ pesijẹ! Awọn ọba Kwara f'ohun ṣọkan, wọn ni 'Gomina AbdulRazaq at'awọn adije lẹgbẹ APC la maa dibo fun l'ọdun 2023'


Nibi ti ọrọ naa de duro bayii, o ti f'oju han gbangba wi pe ko si ẹgbẹ oṣelu meji t'awọn ọba alaye n'ipinlẹ Kwara, paapaa awọn to wa lati ẹkun Ariwa ipinlẹ naa fẹẹ dibo fun ninu eto idibo ọdun 2023 to n bọ lọna yii, to kọja ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.

Laipẹ yii l'awọn ọba alaye to wa lati ẹkun Ariwa Kwara pariwo sita wi pe ki gbogbo awọn oludije ti ko ba ti jade inu ẹgbẹ oṣelu APC lọ jokoo ara wọn, ki wọn si ma ṣe da ara laamu, nitori pe oju awọn ti la si iṣakoso to fẹran araalu d'ọkan.
 
Awọn ọba alaye naa to sọrọ sita sọ pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq l'awọn yoo dibo fun, nitori t'awọn n fẹ ko pada s'ipo naa lẹẹkeji, l'ọdun 2023.

Wọn ni lati ori gomina, titi de ori ipo to kere julọ l'awọn yoo ti ṣagbatẹru ẹgbẹ oṣelu APC lati ri i pe wọn jawe olubori.

Lara awọn ọba naa to sọrọ lọtọọtọ Etsu tilu Patigi, Alaaji Ibrahim Bologi II ati Ẹmir tilu Okuta, Ọmọwe Abubakar Sero sọ peọkan awọn balẹ daadaa lori iṣakoso ẹgbẹ APC n'ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI