Ẹgbẹrun lọna ọgbọn obinrin bọ saye ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 10, 2022

Ẹgbẹrun lọna ọgbọn obinrin bọ saye ni Kwara


Lasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, inu idunnu ati ayọ nla l'awọn obinrin kaakiri ipinlẹ Kwara wa lori bi ijọba ipinlẹ naa ṣe bu ọwọ lu owo iranwọ, ẹgbẹrun lọna ogun naira fun wọn.

Owo ọhun la gbọ pe awọn obinrin olokoowo kekeeke ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn ni wọn yoo jẹ anfaani owo iranwọ naa.

A gbọ pe oṣu mẹfa gbako ni wọn yoo fi jẹ anfaani owo iranwọ naa, ti banki agbaye ṣagbatẹru rẹ.

Ninu atẹjade ti Ọjọgbọn Mamman Ṣaba Jubril to jẹ akọwe ijọba ipinlẹ naa fi sita, o jẹ ko di mimọ pe abẹ eto Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP) ni wọn yoo gbe eto owo ọhun si.

Gbogbo awọn obinrin kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun ni yoo jẹ anfaani owo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI