Ọdun mọkandinlọgọta: AbdulRazaq ki Ọlọfa ku oriire - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 10, 2022

Ọdun mọkandinlọgọta: AbdulRazaq ki Ọlọfa ku oriire


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara lonii, Ọjọru, Wẹside ti ba Ọlọfa tilu Ọffa, Ọba Mufutau Muhammed Gbadamọsi, Eṣuwoye keji yọ fun ti ayẹyẹ ọdun mọkandinlọgọta to pe loke eepẹ.
 
AbdulRazaq, ninu ọrọ ikini rẹ si Ọlọfa, o ṣapejuwe kabiyesi naa gẹgẹ bii eyi to ti mu idagbasoke nla wọ ilu naa.
 
O gbadura ẹmi gigun ati alaafia fun Ọlọfa.
 
Bẹẹ lọ tun gba kabiyesi lamọran lati tubọ maa tẹsiwaju ninu iwa rere rẹ to n mu ilọsiwaju ba ilu naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI