Èmi gangan ni ipò Aborò t'ìlú Ìbèṣè tọ́ sí, kìí ṣe Múléró - Ọmọọba Ìdòwú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 1, 2022

Èmi gangan ni ipò Aborò t'ìlú Ìbèṣè tọ́ sí, kìí ṣe Múléró - Ọmọọba Ìdòwú


Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ni ki ọrọ naa ma pada gba ibomiran yọ lori ọrọ Aboro tilu Ibeṣe, ijọba ibilẹ Yewa South, eyi ti ijọba ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ lu lontẹ.

Lọsẹ to kọja yii ni ijọba ipinlẹ Ogun fi orukọ awọn Ọmọọba kan sita lati di ọba niluu wọn, eyi ti Ọmọọba Rotimi Oluṣeyi Mulero naa wa lara wọn, gẹgẹ bi Aboro tilu Ibeṣe.

Bo tilẹ jẹ pe wahala tabu ipo naa kan niluu Ibeṣe ti wa nilẹ tipẹ, ṣugbọn, ọsẹ to kọja yii ni Gomina Dapọ Abiọdun sọ pe oun ti bu ọwọ lu Ọmọọba Mulero, ni ibamu pẹlu iwe ofin oye jijẹ nipinlẹ naa.

Kete ti Gomina Abiọdun ti kede Ọmọọba Mulero la gbọ pe oriṣiriṣi awuyewuye ti jade wi pe ki i ṣe ẹni ti ipo ọhun tọ si ni ijọba ipinlẹ Ogun kede rẹ.

Nigba to n tako Ọmọọba Mulero gẹgẹ bi Aboro, Ọmọọba Alexander Adegbemiro Idowu sọ pe iwa ojusaaju ni wọn fi yan ẹni to wọn kede rẹ.

O ni ẹjọ naa ti wa nile ẹjọ ti pe, iyẹn nigba ti awọn afọbajẹ ilu Ibeṣe gbabọdi, toun ko si le gba ki wọn rẹ oun jẹ.

Ọmọọba Idowu jẹ ko di mimọ pe oun gangan ni ẹni ti Ifa mu, ni kete ti ọba ana waja.


O tẹsiwaju pe gẹgẹ bi ilana ọba jijẹ niluu naa, o ni awọn ọmọ ọkunrin ni wọn maa n jẹ ọba, ki i ṣe lati idile obinrin, ati pe gẹgẹ bi ẹgbọn, oun lo yẹ nipo naa, ki i ṣe Mulero.

A gbọ pe agba to de si Ọmọọba Idowu lo jẹ ki wọn gbe ipo ọhun fun Ọmọọba Mulero lati di Aboro, eyi ti wọn ni ko bojumu to rara.

Ọmọọba Alexander Adegbemiro Idowu wa rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ogun lati tete gbe ọrọ naa yẹwo, ki wọn si ṣe ohun to tọ, ki wọn si ma ṣe tapa si iṣẹṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI