Ìjọba Kwara kó àwọn bọ́ọ̀sì bọ̀gìnnì f'áwọn aráàlú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 2, 2022

Ìjọba Kwara kó àwọn bọ́ọ̀sì bọ̀gìnnì f'áwọn aráàlú


Lojuna lati jẹ ki igbokegbodo ọkọ to ja geere rọrun, ijọba ipinlẹ Kwara ti ko awọn bọọsi kekeeke sita fun gbogbo awọn araalu lati maa fi gbadun ara wọn.

Ẹgbẹ awọn awakọ lorileede yii, ẹka ti ipinlẹ naa la gbọ pe ijọba fa awọn ọkọ kekeeke ti awọn oloyinbo n pe ni Mini-Bus ọhun fun.

Awọn naa ni ẹgbẹ awakọ Road Transport Employers Association of Nigeria, RTEAN ati National Union of Road and Transportation Workers, NURTW, ni iroyin fi to wa leti pe wọn jẹ anfaani yii.

Nigba to n gba ẹnu Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọrọ, amugbalẹgbẹẹ agba pataki lori ọrọ iranlọwọ fawọn agbegbe (Community Intervention), Ọgbẹni Kayọde Oyin-Zubair lọjọ Satide, Abamẹta to kọja yii, o ni kaakiri igberiko to wa n'ipinlẹ naa l'awọn bọọsi ọhun yoo ṣiṣẹ de.

O ni bọọsi kekeeke ti ko din ni aadọta ni ijọba kọkọ ko silẹ ni ipele akọkọ, eyi ti wọn yoo pin lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee fawọn to ba kun oju oṣuwọn.

Nibẹ lo ti mẹnuba diẹ lara awọn aṣeyọri rẹ, to si ni iranlọwọ to ti ṣẹlẹ labẹ akoso oun ti le ni ẹẹdẹgbẹta naira, lara wọn ni ọgọrun-un kẹkẹ maruwa ti wọn pin lọdun to kọja at'awọn miran.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI