Nnkan de: Arẹgbẹṣọla ati tẹgbọn-taburo ti ha l'Ekoo o, ẹsun Yahuu-Yahuu ni wọn fi kan wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 16, 2022

Nnkan de: Arẹgbẹṣọla ati tẹgbọn-taburo ti ha l'Ekoo o, ẹsun Yahuu-Yahuu ni wọn fi kan wọn


Yoruba lo sọ pe 'iwa rere ni ẹṣọ eniyan', koda bibeli gan-an f'idi rẹ mulẹ pe 'tọ ọmọ rẹ, ki o le fun ọ ni isinmi'. Ọrọ wọnyi ko ri bẹẹ nigba ti ọwọ palaba ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC tẹ ọmọ iya kan naa meji lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti mọ si Yahuu-Yahuu.
 
Ilu Eko la gbọ pe ọwọ palaba awọn mejeeji ti segi, koda, ti wọn sọ pe ṣe ni wọn ko wọn mọ awọn akẹgbẹ wọn ti wọn jọ n lu jibiti ori ayelujara yii.
 
Awọn ti ko din ni marundinlọgbọn la gbọ pe ọwọ tẹ.

Lara wọn ni: Oyewọle Damilọla, Ovin Adekunle, Ovin Nicholas, Ridwan Iyiọla, Arẹgbẹṣọla Tobilọba, Ọladoṣu Saheed, Oseni Ọmọtara, Abel Durotimi, Oyenẹyẹ Rilwan Adetọla, Ọmọrẹgbẹ Destiny Nosa, Evbonaye Ọlalẹyẹ, Adeyẹmọ Abiọla, Temitọpẹ Ajetọnmọbi, Dare-Ilọri Ọrẹoluwa David, Adekanye Ayọdeji Ezekiel, Osagie Harry Odosa ati Arowolo Oluwafẹmi Isaac.

Awọn yooku ni: Agbaje Jackson Babatunde, Owolabi Temiloluwa Dominion, Fadipẹ Biọdun Idris, Agbayọ Mọshood Oriyọmi, Sylvester Evans, Ọṣọkọya Ọlaoluwa Muritalah, Ọmọtoye Collins Oluwaṣeun ati Hassan Abdulwahab Ọladimeji.

Gẹgẹ ajọ EFCC ṣe ṣalaye, wọn ni Damilọla, Adekunle, Nicholas ati Iyiọla lọwọ kọkọ tẹ lagbegbe Palmcity Estate to wa ni Lẹkki, ipinlẹ Eko, iyẹn lọjọ kẹwaa, oṣu yii, ko to di pe ọwọ tẹ awọn yoo ninu ọgba City-View Estate, to wa lopopona ilu Eko si Ibadan lọjọ kejila, ọsu yii.
 
Olobo kan ti wọn lo ta awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC ko to di pe wọn bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn, ti aṣiri awọn eeyan wọnyi si tu nibi ti wọn ti jaye famile-ki-n-tutọ.
 
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn ni foonu olowo nla ati kọmouta alagbeeka loriṣiriṣi, eyi ti wọn fi n lu jibiti.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI