O pari o! Awọn ọba alaye yẹyẹ Rafiu Ibrahim nita gbangba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 24, 2022

O pari o! Awọn ọba alaye yẹyẹ Rafiu Ibrahim nita gbangba


Ọrọ buruku toun tẹrin l'ọsan oni, nigba ti wọn sọ pe awọn ọba alaye ti wọn wa ni ipo kẹrin yẹyẹ Sẹnetọ Rafiu Ibrahim, oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Sẹnetọ Ibrahim lo ranṣẹ pe awọn ọba naa pẹlu ẹtanjẹ wi pe gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq lo fẹẹ ri wọn lati ba wọn ṣe ipade.

Wọn ni kete ti wọn de ibi ipade naa, iyẹn ni otẹẹli Intercontinental to wa lagbegbe Ganmo, lati maa jade kuro niluu Ilọrin ni wọn ṣẹṣẹ mọ pe pẹlu ẹtanjẹ ni wọn fi ranṣẹ pe wọn.

A gbọ pe oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba lo fẹẹ ba wọn ṣe ipade idankọnkọ lati le ṣe iranwọ fun un ninu eto idibo to n bọ lọna yii.

Lara awọn to fi iṣẹlẹ ọhun to wa leti sọ pe awọn ọba naa ti n fura pe Gomina AbdulRazaq ko le pe wọn wa si otẹẹli fun ipade, ti yoo ba pe wọn, yala ko jẹ si ilegbe awọn gomina tabi ọfiisi gomina ni ipade yoo ti waye.

Wọn ni ohun ti awọn ọba naa n sọ ni pe nipa ẹtanjẹ ni asofin agba ọhun fi ranṣẹ pe wọn, ati pe to ba de ibi to n foju sọna fun naa, ẹtanjẹ ni yoo pọ fun un.

Nigba ti wọn rii pe kii ṣe gomina lo ranṣẹ pe wọn lotitọ, ṣe ni wọn fibinu kuro níbẹ, ti wọn si n kilọ fun oludije ọhun lati ma ṣe gbiyanju nnkan to ṣe naa mọ lailai.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI