2023: Tinubu nikan lo kaju oṣuwọn lati dari orileede Naijiria - AbdulRazaq fọwọ sọya - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 18, 2022

2023: Tinubu nikan lo kaju oṣuwọn lati dari orileede Naijiria - AbdulRazaq fọwọ sọya


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti f'ọwọ sọya nita gbangba wi pe ẹnikan ṣoṣo to le mu orileede Naijiria de ilẹ ileri lakoko yii ni Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu.
 
AbdulRazaq lo sọrọ yii lakoko to n b'awọn ọmọ orileede yii to n gbe lẹyin odi sọrọ l'opin ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii.
 
Nibẹ lo ti sọ pe ki gbogbo wọn dide lati polongo ibo fun Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Tinubu l'ọdun 2023.
 
O ni yatọ si pe wọn n polongo ibo fun Tinubu, o ni ki gbogbo wọn tun ba ara awọn sọrọ lati wa a dibo fun ẹni ti ipo naa tọ si, to si le ṣe ohun t'awọn araalu n fẹ.
 
Ilu Newark, New Jersey, ilẹ Amẹrika ni AbdulRazaq ti sọrọ naa nibi akanṣe eto The Bola Ahmed Tinubu (BAT) Summit (Awards & Dinner), eyi t'awọn ọmọ Naijiria to n gbe nibẹ ṣagbatẹru ẹ.
 
AbdulRazaq, ti ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ APC, Oloriewe Raheem Adedoyin ṣoju fun gba wọn lamọran lati ma ṣe dawọ ipolongo wọn duro nipa bi ba awọn eeyan sọrọ nipa idibo ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI