O ṣẹlẹ! Eegun rẹpẹtẹ yawọ ṣọọṣi, wọn lu awọn ọmọ ijọ lalubami - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 19, 2022

O ṣẹlẹ! Eegun rẹpẹtẹ yawọ ṣọọṣi, wọn lu awọn ọmọ ijọ lalubami


Ọrọ buruku toun tẹrin lọjọ Aiku, Sannde to kọja nigba ti wọn l'awọn eegun meloo kan yawọ ṣọọṣi, o si kona fun gbogbo awọn olujọsin to wa nibẹ.

Abule Shikal, to wa nijọba ibilẹ Lantang South, ipinlẹ Pleateu ni ṣọọṣi naa ti a fi orukoọ bo laṣiri wa, ti wọn si lu olori at'awọn ọmọ ijọ lalubami nibẹ.

Yatọ si eyi, wọn l'awọn eegun naa tun ba gbogbo ohun elo orin, to fi mọ ọpọ dukia ti wọn n lo ni ṣọọṣi naa, lati da isin ọjọ Isinmi wọn ru.

Asiko ti wọn ni isin n lọ lọwọ la gbọ pe awọn eegun naa, to fi mọ awọn ọmọ ẹyin wọn yawọ ṣọọṣi ọhun lati da nnkan ru mọ wọn loju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI