AbdulRazaq ba Kashim Shettima yọ lori ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹrindinlọgọta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 2, 2022

AbdulRazaq ba Kashim Shettima yọ lori ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹrindinlọgọta


Lonii ni igbakeji oludije s'ipo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, iyẹn Alaaji Kaṣhim Ṣhẹttima n ṣayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹrindinlọgọta, ti awọn jankanjankan kaakiri agbaye si n ba a yọ.
 
B'awọn eeyan ṣe n ba Shettima yọ ayọ naa, ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ko gbẹyin lati darapọ mọ awọn to n fi ọrọ ikini ranṣẹ si agba oloṣelu naa.
 
Kashim Shettima ni gomina ana n'ipinlẹ Borno, to si tun jẹ ọkan lara awọn aṣofin agba orileede yii.

Ninu ọrọ ikini rẹ, AbdulRazaq ṣapejuwe Shettima gẹgẹ bi aṣiwaju rere to ṣee tẹle, to si ṣee f'ọkan tan, paapaa julọ lakoko yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI