Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe ẹdun ọkan nla lo jẹ f'oun lati padanu ọkan pataki lara awọn agba alẹnulọrọ ni ipinlẹ naa lakoko yii.
AbdulRazaq lo sọrọ naa lonii, ọjọ Ẹti, Furaide, nibi eto adura ati isinku Ambassador Abdulkadir Muhammad Sambo Imam nile ẹ to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ naa.
Nibi eto naa ti awọn agbaagba ati alẹnulọrọ n'ipinlẹ naa peju si, ni Gomina AbdulRazaq ti ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi ọkan lara awọn ẹbun pataki ti Ọlọrun fi ta ipinlẹ naa lọrẹ.
O ni oloogbe naa ti ko ipa ribiribi to jọju ninu idagbasoke orileede Naijiria, paapaa ipinlẹ Kwara lapapọ.
No comments:
Post a Comment