Ọkan lara awọn ajinigbe to ji ẹnikan gbe lagbegbe Shao, ipinlẹ Kwara lo ti pade iku ojiji s'ọwọ ọlọpaa lẹnu iṣẹ buruku to yan laayo.
Gẹgẹ bi Ọkasanmi Ajayi to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ṣe ṣalaye f'awọn akọroyin laipẹ yii, o ni awọn ọlọpaa lo yawọ ibudo awọon ajinigbe naa lati gba ẹni ti wọn jigbe silẹ lahamọ wọn.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtala, oṣu ti a wa yii ni iroyin jade sita pe awọn ajinigbe kan ti ji Arabinrin Afusat Lawal ati ọmọkunrin rẹ, Taofeek Lawal gbe ni nnkan bi agogo mọkanla kọja oogun iṣẹju alẹ, lagbegbe Shao.
Bi wọn ṣe ji awọn mejeeji gbe salọ ni wọn ti n beere owo lọwọ mọlẹbi wọn, ti a si gbọ pe wọn ko obitibiti owo silẹ fun wọn.
Bi wọn ṣe gba owo naa tan l'awọn ọlọpaa at'awọn fijilante dide lati lọ koju wọn, ti aṣiri wọn si tu nibi ti wọn ti n pin owo ti wọn gba lori awọn ti wọn jigbe.
Wọn ni loju ẹsẹ ti wọn ti foju kan awọn ọlọpaa ni wọn ti doju ibọn kọ wọn, ṣugbọn t'awọn ọlọpaa naa da a pada fun wọn. Igba ti wọn ṣakiyesi pe agbara wọn ko fẹẹ ka awọn ọlọpaa lo jẹ ki wọn juba ehoro, to si jẹ pe ibọn ba ọkan lara wọn, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji loju ẹsẹ.
Lara awọn nnkan ti wọn ri ko nibẹ ni ibọn ẹlẹnu kan, mọtọ Honda Accord ti nọmba idanimọ rẹ jẹ LAGOS GJ 52 LSR ti wọn fi n ṣiṣẹ ibi wọn, ati ọpọlọpọ owo.
A gbọ pe iwadii ṣi n lọwọ lati rọwọ to awọn yooku to na papa bora, lati le fi wọn jofin.
Bẹẹ la gbọ pe awọn mejeeji ti wọn jigbe ni wọn ti wa pẹlu awọn mọlẹbi wọn layọ ati alaafia.
No comments:
Post a Comment