Iṣẹ idagbasoke ti Gomina AbdulRazaq n ṣe ni Kwara ti yi aye awọn olukọ ati akẹkọọ pada si rere - Awọn ọga agba ile-ẹkọ girama - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 15, 2022

Iṣẹ idagbasoke ti Gomina AbdulRazaq n ṣe ni Kwara ti yi aye awọn olukọ ati akẹkọọ pada si rere - Awọn ọga agba ile-ẹkọ girama


Agabrijọ ẹgbẹ awọn ọga agba l'awọn ile-ẹkọ girama kaakiri ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq dawọ le nipinlẹ naa ti yi aye ọpọ awọn olukọ ati akẹkọọ pada si rere.
 
Wọn ni gbogbo olukọ patapata ni wọn ti mọ riri ati pataki iṣakoso Gomina AbdulRazaq n'ipinlẹ Kwara, eyi ti wọn sọ pe iru ẹ ko tii ṣẹlẹ ri nipinlẹ naa.
 
Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii l'awọn ọga agba naa ti a mọ si Principal kaakiri ipinlẹ Kwara sọrọ naa jade, ti wọn si ni alaimoore l'awọn to ba sọ pe wọn ko ri ipa ti gomina n ko ninu iṣẹ idagbasoke to n ṣẹlẹ kaakiri.
 
Nibẹ ni wọn tun ti gbe oṣuba rabandẹ fun gomina lori eto KwaraLEARN ti wọn tun ṣẹṣẹ gbe dide, eyi ti wọn lo jẹ k'awọn olukọ ba ẹgbẹ pe lawujọ eto ẹkọ agbaye.
 
Ipade naa to waye pẹlu gomina niluu Ilọrin lo fun wọn lanfaani lati sọ erongba wọn lori awọn iṣẹ ti AbdulRazaq n ṣe lẹka eto ẹkọ, ati awọn ibi ti iṣẹ tun ku si.
 
Awọn ọga agba ti ko din ni ọọdunrun la gbọ pe wọn wa nibi ipade naa, to fi mọ awọn alẹnulọrọ lẹka eto ẹkọ n'ipinlẹ Kwara.
 
Nigba ti wọn n gbe oriyin fun gomina, paapaa lori ọrọ owo oṣu ati agbegbe ikẹkọọ to fanimọra, wọn rọ ọ lati tun pada gbe eto k'awọn akẹkọọ maa gbe ile-ẹkọ dide, eyi to ti ku tipẹtipẹ.
 
Bẹẹ ni wọn rọ gomina lati ṣe iranwọ lori awọn gbese to ba nilẹ lọdun 2019, ati rira awọn ohun elo l'awọn yara idanilẹkọọ ti a mọ si labouratories.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI