Awọn afurasi to pa oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi dero ẹwọn l'Ékìtì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 14, 2022

Awọn afurasi to pa oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi dero ẹwọn l'Ékìtì


Ọwọ awọn ẹṣọ aabo ara-ẹni-laabo ilu ti a mọ si Sifu Difẹnsi ti tẹ awọn mẹrin kan lori iku oṣiṣẹ wọn ti wọn pa danu laipẹ yii nipinlẹ Ekiti.

Lẹyin ti wọn pa oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Ṣẹgun Ayebulu, la gbọ pe wọn tun ji awọn mọlẹbi rẹ gbe salọ.

A gbọ pe ọwọ awọn fijilante to wa ni ijọba ibilẹ idagbasoke Ajoni, ipinlẹ Ekiti lo tẹ awọn afurasi ọdaran naa.

Ọgbẹni Micheal Ogungbemi to jẹ alaga ijọba ibilẹ idagbasoke agbegbe naa ninu ọrọ rẹ sọ pe asiko ti awọn fijilante naa n ṣiṣẹ lọ ni wọn kofiri wọn, ti wọn koju wọn, iyẹn ni ẹnubode Ekiti si Kwara.

Ibọn AK-47 meji la gbọ pe wọn gba lọwọ wọn, ko to di pe wọn ko wọn lọ si teṣan ọlọpaa Ikọle Ekiti fun itẹsiwaju iwadii.

A gbo pe ọjọ kẹta, oṣu yii ni wọn yinbọn pa Ayebulu lopopona Oke-Ako, Irele-Ekiti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI