Nítorí Tinubu, àwọn obìnrin ilẹ̀ Yorùbá fẹ́ẹ́ ṣe ìwọ́de nlá l'Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 15, 2022

Nítorí Tinubu, àwọn obìnrin ilẹ̀ Yorùbá fẹ́ẹ́ ṣe ìwọ́de nlá l'Abẹ́òkúta


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari patapata bayii fun ẹgbẹ àwọn obinrin to n ṣe iwọde ipolongo idibo aarẹ fun Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lati pejọ siluu Abẹokuta.

Ipade nla kan la gbọ pe ẹgbẹ awọn obinrin naa labẹ aburada ẹgbẹ kan ti wọn pe ni 'Yoruba Women For Tinubu' fẹẹ ṣe niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lati rii pe baba naa jawe olubori.

Yatọ si pe awọn ọmọ ẹgbẹ naa wa kaakiri orileede Naijiria, a tun gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ naa tun l'awọn alatilẹyin kaakiri agbaye.

Ipade ti wọn fẹẹ ṣe yii, ni iroyin tun fi to wa leti pe wọn fẹẹ lo anfaani ẹ lati fi rin fun ipolongo fun oludije sipo aarẹ Naijiria, eyi ti wọn pe ni "One Million Women Walk", eyi to fẹẹ waye niluu Abẹokuta.Ọjọru, Wẹsidee, iyẹn ọjọ kọkanlelogun, oṣu ti a wa yii la gbọ pe wọn fẹẹ rin irin naa lati fi ba gbogbo awọn obinrin sọrọ nipa ṣiṣagbatẹru Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ninu idibo ọdun 2023 to n bọ lọna.

Ninu atẹjade ti alakoso ẹgbẹ naa, Kọmureedi Toyọ Busayọ bu ọwọ lu lonii, Ọjọbọ, Tọsidee sọ pe ẹnikan ṣoṣo to le mu orileede Naijiria de ilẹ ileri ni Tinubu, idi ree to fi l'awọn ṣetan lati tẹle e.

Busayọ jẹ ko di mimọ pe Papa Iṣere MKO Abiọla to wa ni Kutọ l'awọn yoo ti pejọ laago mẹwaa aarọ ọjọ naa, nibi ti wọn yoo ti rin lọ si ọfiisi gomina ipinlẹ Ogun to wa ni Oke-Mọsan, Abẹokuta, ko to di pe wọn dari lọ si ikorita Panṣẹkẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI