Àwọn obìnrin ẹgbẹ̀rún lọnà ọgbọ̀n tún bọ́ s'áyé ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 21, 2022

Àwọn obìnrin ẹgbẹ̀rún lọnà ọgbọ̀n tún bọ́ s'áyé ní Kwara


Ṣe ni idunnu tun ṣubu lu ayọ awọn obinrin, paapaa awọn to n ta ọja kaakiri ipinlẹ Kwara, nigba ti wọn bẹrẹ sii gba owo iranwọ, ẹgbẹrun lọna ogun naira.

Awọn obinrin ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn (30,000 women) la gbọ pe wọn yoo jẹ anfaani naa lonii Ọjọru, Wẹsidee.

Kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindilogun to wa nipinlẹ Kwara la gbọ pe wọn ti fẹẹ jẹ anfaani naa lai ṣe ojusaaju ẹnikẹni.

AWIKONKO gbọ pe banki agbaye lo ṣagbatẹru eto naa, labẹ eto Nigeria for Women Project, eyi ti ileeṣẹ Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP) ti wọn tun n pe ni 'Owo Iṣowo' ṣe abojuto ẹ.

Alakoso fidihẹ agba fun ileeṣẹ KWASSIP, Abdulquawiy A. Olododo, ninu ọrọ rẹ sọ pe ijọba ibilẹ Ilorin West, Ilorin South, ati Asa ni wọn yoo ti kọkọ bẹrẹ lonii, ko to di pe wọn tẹsiwaju l'awọn ọjọ miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI