Ọga agba pata ni Nigerian Institute of Leather and Science Technology (NILEST), eyi to wa niluu Zaria, Muhammad Yakubu ti gba ijọba orileede Naijiria lamọran lati f'ofin de jijẹ Pọnmọ lorileede yii.
Muhammad Yakubu sọ pe Pọnmọ t'awọn eeyan fi n ṣe ẹran jẹ ni gbogbo igba ko ni ohun iṣara loore kankan to wa nibẹm idi ree to fi sọ pe ki ijọba apapọ f'ofin de e.
Ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii ni Muhammad Yakubu sọrọ naa jade
O tẹsiwaju pe jijẹ awọ ẹran ti ko ni ohun iṣaraloore kankan ninu jẹ ohun ti ijọba apapọ gbọdọ fi ofin de, lati le mu ki eto ọrọ aje orileede Naijiria lọ soke sii
Yakubu tun fi kun un pe oun at'awọn kan ni ileeṣẹ toun di mu yoo dide lati lọ si ile igbimọ aṣofin at'awọn ipinlẹ kan, lati le jẹ ki wọn gbe ofin dide lati fifofin de e.
No comments:
Post a Comment