Aye o! Iyaale ile dawati n'ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 12, 2022

Aye o! Iyaale ile dawati n'ipinlẹ Ogun


Titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, ni ko tii sẹni to le sọ pato ibi ti iyaale ile, ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Arabinrin Sandra Ọmọbọlanle Ataruno wa, ti wọn si l'awọn mọlẹbi rẹ ti wa ninu aawẹ ati adura lati rii.
 
Ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii la gbọ pe Arabinrin Sandra jade kuro nile ẹ to wa lagbegbe Ijoko Ọtta.
 
Wọn ni ko to kuro nile, o dagbere pe agbegbe Oju Oore loun n lọ, iyẹn ni nnkan bi aago mẹta ọsan, ṣugbọn ti wọn sọ pe ko pada sile latigba naa titi di asiko yii.
 
Gbogbo akitiyan awọn mọlẹbi obinrin naa lati mọ ibi to wa titi di asiko yii la gbọ pe o ja si pabo, ti wọn si ti lọ fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti lati ran wọn lọwọ.
 
Awọn ẹbi naa ni wọn wa n rawọ si gbogbo ọmọ Naijiria lati ta ileeṣẹ ọlọpaa to ba sunmọ wọn, tabi awọn mọlẹbi rẹ lolobo, bi wọn ba kofiri rẹ.
 
Lara awọn ẹrọ ibanisọrọ ti ẹ maa pe ree, bi ẹ ba kofiri obinrin naa.
 
Emmanuel Ataruno (Ọkọ rẹ) 07033557710;
Arabinrin Funmilọla Adefabijo (Aburo rẹ) 08036276924;
Ọgbẹni Ọlaifa Emmanuel (Alaga adugbo to n gbe) 08068920051.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI