Ọmọọba ran awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn jẹ agbanipa si Kabiyesi l'aafin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 12, 2022

Ọmọọba ran awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn jẹ agbanipa si Kabiyesi l'aafin


B'awọn kan ṣe n sọ pe ọmọọba to ran awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn jẹ agbanipa si baba rẹ kii ṣe ojulowo ọmọ, bẹẹ l'awọn kan n sọ pe ọmọ ale pọmbele ni, t'awọn kan si n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe eedi lo dii, ṣugbọn ti a ko tii le f'idi rẹ mulẹ titi di asiko yii.
 
AWIKONKO gbọ pe Ọba ilu Gbokoto, nitosi Ọja Ọdan, ipinlẹ Ogun, Ọba G. O OlukunleIroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ni ọkan lara awọn ọmọ ẹ ran awọn agbanipa sii lati pa a danu, ṣugbọn ti ori pada ko o yọ.

Wọn ni aawọ kan lo ṣẹlẹ laaarin kabiyesi ati olori rẹ, to jẹ iya ọmọ naa, eyi ti wọn sọ pe ọrọ naa fẹẹ dabi ẹni pe ko fẹẹ ni iyanju.
 
Nigba ti wọn sọ pe ọmọ naa rii pe o ṣee ṣe ki ọrọ naa pada gba ibi ti wọn ko lero yọ, lo mu ko ran awọn ọrẹ rẹ, ti wọn jẹ ẹlẹgbẹ okunkun Eiye si Kabiyesi lati gbẹmi rẹ.
 
Ọjọ Aiku, Sannde, ana la gbọ pe awọn agbanipa naa yawọ aafin Kabiyesi pẹlu ibọn, at'awọn nnkan ija oloro, pẹlu erongba lati ran kabiyesi lọ s'ọrun aremabọ.
 
Nibẹ ni wọn l'awọn to wa nitosi ti ranṣẹ s'awọn ọlọpaa Ọja-Ọdan lati wa a doola ẹmi ati dukia awọn eeyan, paapaa ti kabiyesi, ti awọn ọlọpaa naa ko si fi falẹ rara.
 
Wọn ni loju ẹsẹ táwọn ọlọpaa ti de aafin, ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti dabọn bo wọn, ti awọn ọlọpaa naa ko si fi falẹ rara, t'awọn naa fi da a pada.
 
Lẹyin o rẹyin lọwọ pada tẹ mẹfa ninu wọn, nigba ti wọn l'awọn yooku na papa bora.
 
Awọn naa ni nnkan bi aago mẹrin kọja iṣẹju marundinlọgbọn ni Michael Ayọdele, Monday Samuel, Ademọla Matthew, Hammẹd Jẹlili, Ogundele Ojeh ati Sunkanmi Fadina.
 
Nigba to n gbe iroyin ọhun sita laipẹ yii, Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ pe awọn agbanipa ọhun ti jẹwọ pe ọkan lara awọn ọmọ kabiyesi lo ran wọn niṣẹ, ati pe ọmọ naa ti juba ehoro.
 
Ọga ọlọpaa, CP Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ, ati pe ọwọ gbọdọ tẹ ọmọ to na papa bora naa, at'awọn ti wọn tun jọ lọ, lati le fi wọn j'ofin iwa ọdaran.
 
Ibọn ati ọta ibọn la gbọ pe wọn gba lọwọ wọn lasiko t'ọwọ tẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI