Babangida to fi iṣẹ ijọba lu jibiti miliọnu mẹẹdogun naira wọ gau ni Kano - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 22, 2022

Babangida to fi iṣẹ ijọba lu jibiti miliọnu mẹẹdogun naira wọ gau ni Kano


Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ti rọwọ to ọkunrin kan ti wọn pe orukọ pe orukọ rẹ ni Hassan Babangida, lori ẹsun wi pe o fi iṣẹ ijọba lu awọn eeyan ni jibiti.
 
Owo to din diẹ ni miliọnu mẹẹdogun, N14,950,000 naira la gbọ pe Babangida lu jibiti ẹ, pẹlu ẹtanjẹ lati ba awọn to n wa iṣẹ ijọba wa iṣẹ si ileeṣẹ ijọba.

Ilu Kano la gbọ pe ọwọ palaba Babangida ti segi, lẹyin ti wọn ta awọn oṣiṣẹ ajọ naa lolobo.
Wọn ni ṣe lo n purọ f'awọn eeyan wi pe oun le ba wọn ri iṣẹ si ẹka ileeṣẹ ijọba yoowu lorileede yii, ti wọn yoo si maa gba owo gidi.

Agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Wilson Uwujaren nigba to n tu aṣiri naa sita l'Ọjọru, Wẹsdiee, ọsẹ yii sọ pe ẹnikan to n jẹ Usman Rilwan ni Babangida gba N14,950,000 naira lọwọ ẹ, pẹlu ẹtanjẹ lati ba a wa iṣẹ.
 
O ni Rilwan lo wa fi ẹjọ sun pe ẹnikan lu oun ni jibiti.
 
Rilwan sọ pe lẹyin toun san owo naa fun Babangida, lo f'oun ni iwe wi pe wọn ti gba oun si iṣẹ, eyi to loun pada rii pe ayederu lasan ni, kii ṣe ojulowo.

Uwujaren ti wa fidi rẹ mulẹ pe Babangida yoo f'oju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI