O pari! Ọwọ Amọtẹkun tun tẹ ọdaran marundinlaadọta l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 22, 2022

O pari! Ọwọ Amọtẹkun tun tẹ ọdaran marundinlaadọta l'Ondo


Ọwọ ileeṣẹ eto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka ti ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn marundinlaadọta kan ti wọn fura si pe ọdaran ni wọn, ti wọn si ti n ṣe iwadii wọnn lọwọ.
 
Aarin ọsẹ meji la gbọ pe ọwọ tẹ gbogbo wọn ni agbegbe ọtọọtọ laaarin ipinlẹ naa
 
Nigba to n f'oju wọn han lagbegbe Alagbaka niluu Akurẹ, olori awọn Amọtẹkun n'ipinlẹ naa, Adetunji Adelẹyẹ sọ pe mẹjọ ninu awọn ọdaran naa jẹ ajinigbe.
 
Amotekun arrests 45 suspected kidnappers, rapists and armed robbers in Ondo  
Adetunji sọ pe awọn to gbọ nipa awọn ọdaran naa tipẹtipẹ, eyi to jẹ ki awọn bẹrẹ iṣẹ iwadii to mu ki ọwọ tẹ gbogbo wọn.
 
O wa sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ, ko to di pe wọn f'oju wọn ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI