Ẹ fura s'áwọn jàgùdà olóṣèlú tí wọ́n fẹ́ẹ́ fi owó ra ìbò lọ́wọ́ yín - Ọnarebu Harrison - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 15, 2022

Ẹ fura s'áwọn jàgùdà olóṣèlú tí wọ́n fẹ́ẹ́ fi owó ra ìbò lọ́wọ́ yín - Ọnarebu Harrison


Oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Congress, AAC, Ọnarebu Harrison Adeyẹmi ti gba gbogbo araalu lamọran lati ṣọra fawọn oloṣelu ti wọn n kaakiri lasiko yii lati fi owo ra ibo lọdun 2023.

Ọnarebu Harrison Adeyẹmi sọ pe oni jibiti, jaguda ti wọn n wa gbogbo ọna lati wa ni ipo oṣelu nitori iwa ti ara ẹni nikan to n ba wọn kaakiri.

Laipẹ yii ni Ọnarebu Harrison sọrọ naa jade nibi ifọrọwerọ to ṣe lori redio niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun nipa ipinlẹ naa.

Nibẹ lo ti sọ pe bi wọn ko ba gba oloṣelu to n gbe owo kaakiri lati ra ibo oludibo, yoo fun wọn lanfaani lati ma ṣe dibo fun iṣakoso rederede lọdun 2023.

O ni ki awọn araalu dibo fun awọn to kaju oṣuwọn lati ṣe ijọba, ati pe oun lẹni kan sosorto kaju oṣuwọn lati di ipo gomina ipinlẹ Ogun lakoko yii.

Siwaju sii lo sọ pe ko le gba oun ju oṣu mẹfa lọ lati dẹkun gbogbo aisi eto aabo to n ba ipinlẹ naa finra.

1 comment:

  1. He's contesting under African Action Congress not African Alliance Congress

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI