Ẹ ma ṣe gbe ara le orukọ awọn oludije to jade lẹgbẹ oṣelu PDP, idajọ ile-ẹjọ n bọ laipẹ - Ṣẹgun Ṣowunmi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 21, 2022

Ẹ ma ṣe gbe ara le orukọ awọn oludije to jade lẹgbẹ oṣelu PDP, idajọ ile-ẹjọ n bọ laipẹ - Ṣẹgun Ṣowunmi


Oludije s'ipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ṣẹgun Ṣowunmi ti gba awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lamọran lati ma ṣe gba awọn orukọ ti ajọ eleto idibo fi sita lẹgbẹ oṣelu naa wọle.
 
Ṣowunmi sọ pe ile ẹjọ nikan lo le sọ awọn ti yoo wa ninu iwe ajọ eleto idibo fun idibo ọdun 2023 to n bọ lọna.

O sọ pe ẹjọ ṣi wa niwaju ile ẹjọ, ti idajọ ko si tii waye.

Agbẹnusọ tẹlẹ fun oludije s'ipo aarẹ lọdun 2019, Alaaji Atiku Abubakar naa sọ pe gbogbo awọn to ṣi n dunnu lasiko yii, lẹyin ti ajọ INEC gbe orukọ wọn jade lo ṣi maa lulẹ nigba ti idajọ ba waye.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "A ṣi wa nile ẹjọ, ati bẹẹbẹẹlọ, awọn orukọ ti ajọ INEC fi sita fun ipinlẹ Ogun ko ni nnkan ṣe pẹlu eto idibo, ayafi bi ile ẹjọ ba paṣẹ.

"Ẹ jẹ ki awọn alaimọkan ṣi maa yọ. Wọn maa to o lulẹ. Ninu yara ikọkọ wọn, wọn mọ eyi daju. Awọn araalu to mọ bo ṣe n lọ naa mọ eyi daju. Ẹ ma jẹ ki ẹnikan tan ẹnikan jẹ.

"Ile ti a ba fi aibofin mu to, ko le duro lailai. Ori idajọ ododo la duro le."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI