Trump tun yẹyẹ Biden lẹyin isinku Ọbabinrin Elizabeth keji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 21, 2022

Trump tun yẹyẹ Biden lẹyin isinku Ọbabinrin Elizabeth keji


Aarẹ ana nilẹ Amẹrika, Donald Trump ti yẹyẹ Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden lori ibi ti wọn fi aaye ijokoo rẹ si, to si ni iwọsi nla ni wọn fun Aarẹ Amẹrika.
 
Aaye kẹrinla la gbọ pe Aarẹ Biden jokoo si nibi eto isinku Ọbabinrin ilẹ Amẹrika, Ọbabinrin Elizabeth to waye l'ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni Westminster Abbey.
 
Royal Vault to wa ni Winsdor Castle ni wọn sinku olori ilẹ Amẹrika ati ajọ agbaye ti Commonwealth tẹlẹ naa si.
 
Trump ninu ọrọ rẹ sọ pe wọn ko bu ọla to yẹ fun ipo Aarẹ ilẹ Amẹrika, eyi to ni iru ẹ ko le ṣẹlẹ kani oun ṣi wa n'ipo naa ni.
 
Ori ikanni ayelujara ti Truth Social ni Trump ti sọrọ naa jade lẹyin isinku.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Eyi lohun to ti ṣẹlẹ si ilẹ Amẹrika laaarin ọdun meji perete. Ko si ibọwọ kankan rara! Ju gbogbo rẹ lọ, asiko gidi ree lati mọ awọn olori f'awọn orileede agbaye kẹta.
 
“Bi mo ba ṣi wa n'ipo aarẹ, wọn ko le gbe mi lọ jokoo si ẹyin nibẹ yẹn — ati pe orileede wa yoo ti yatọ si ipo to wa bayii!”.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI