Ọwọ ti tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun mejilelogun kan, Ibrahim Umar lori ẹsun wi pe o gun mama rẹ baṣubaṣu nitori ọrọ ti ko to nnkan, to si ti n bẹbẹ pe iṣẹ eṣu ni.
Ijọba ibilẹ Michika to wa ni Ariwa Adamawa n'iṣẹlẹ naa ti waye laipẹ yii.
Mama naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Hajiya Lami Mallum, ni iroyin ti fi ye wa pe o ti wa nibi to ti n gba itọju, ti ọmọ rẹ si wa lọgba ẹwọn.
Nigba to n f'oju ba ile ẹjọ Majisireeti to wa nilu Yola, Ibrahim sọ pe ṣe lo dabi ẹfun f'oun nigba toun pẹlu mama oun jọ n jiyan lori ọrọ kan.
O ni ọrọ naa lo bi oun ninu, paapaa nigba ti mama oun ko fẹẹ gba ọrọ oun, eyi lo fa to loun fi lọ yọ ọbẹ lati gun mama rẹ.
Ninu ọrọ adajọ ile ẹjọ naa, Mohammed Buba, o paṣẹ pe ki wọn ṣi lọ fi Ibrahim sọgba ẹwọn titi di ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ti igbẹjọ yoo tun waye.
Ọjọ kejila, oṣu yii la gbọ ariyanjiyan waye laaarin Ibrahim ati mama rẹ, to si fa ija laaarin wọn. Pẹlu ibinu la gbọ pe o fi ọbẹ yọ, to si gun mama rẹ, Hajiya Lami ni oju.
No comments:
Post a Comment