Ijọba Ondo sinku mẹrindinlẹẹdẹgbẹta lọjọ kan ṣoṣo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 21, 2022

Ijọba Ondo sinku mẹrindinlẹẹdẹgbẹta lọjọ kan ṣoṣo


Ijọba ipinlẹ Ondo ti sin awọn oku ti ko din ni mẹrindinlẹẹdẹgbẹta (496), ti awọn mọlẹbi wọn ko wa gba, paapaa awọn oku ti wọn ko mọ awọn to ni wọn.
 
Ohun ti a gbọ ni pe igbesẹ yii waye lati le jẹ ki aaye wa l'awọn ile igbokusi, iyẹn Mọṣuari to wa nipinlẹ naa.
 
Lara awọn mọṣuari ti wọn ti sin ọpọ oku nibẹ ni eyi to wa niluu Akurẹ ati ilu Ondo, State University of Medical Science Teaching Hospital, UNIMEDTH.
 
Gẹgẹ bi Bisi Lawani, to jẹ olori ẹka iroyin ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ naa ṣe sọ, o ni lẹyin abẹwo ti wọn ṣe lo s'awọn ọsibitu kaakiri ipinlẹ naa, awọn rii pe dandan ni lati palẹmọ awọn oku to ti pẹ kuro nibẹ, lati le gba awọn oku miran laaye.

Nigba toun naa n b'awọn akọroyin sọrọ, oludamọran pataki fun Gomina Oluwarotimi Akeredolu lori ọrọ ilera, Ọjọgbọn Dayọ Faduyile kọminu lori b'awọn oku ṣe pọ kaakiri ile igbokusi.
 
O ni eyi yoo fi aaye ati anfaani silẹ lati jẹ ki wọn tun awọn ile igbokusi naa ṣe, ki wọn si tun awọn to yẹ kọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI