Epo Disu l'awọn eleyii n jigbe kaakiri ipinlẹ Ogun k'ọwọ So-Safe Corps too tẹ wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 24, 2022

Epo Disu l'awọn eleyii n jigbe kaakiri ipinlẹ Ogun k'ọwọ So-Safe Corps too tẹ wọn


Ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe Corps ti jẹ ko di mimọ pe l'opin ọsẹ yii pe awọn tun ti ṣe aṣeyọri nla nipa rirọwọ to awọn marun-un kan ti wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn maa ji epo rọbii ti Disu, iiyẹn Diesel gbe.

Abdullah Mohamed, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn; Lambo Lack, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta; Joel Dawab, ẹni ogoji ọdun; Wellplus Masua, ẹni ọdun mẹrirnlelaadọta ati Seidu Ibrahim, toun jẹ ọmọ ogun ọdun l'awọn maraarun-un tọwọ tẹ.
 
Ohun ti a gbọ ni pe agbegbe Ṣiun to wa n'ijọba ibilẹ Ọbafẹmi-Owode lọwọ ti tẹ wọn, nibi ti wọn ti n ji Disu naa gbe lọwọ, iyẹn l'Ọjọru, Wẹsidee to kọja yii.
 

Awọn oṣiṣẹ So-Safe Corps, ti ẹkun Owode Ẹgba ni aṣiri wọn tu si lọwọ, ni nnkan bi aago mẹjọ aabọ ale ọjọ naa.
 
Wọn ni Disu ti ileeṣẹ kan to n ṣe opopona gbe silẹ lati lo fun iṣẹ wọn láwọn eeyan yii lọ jigbe, ko to di pe akara wọn tu s'epo. Bẹẹ la gbọ pe kii ṣe akọkọ ree ti wọn yoo jale Disu naa, ṣugbọn ti iṣu ti pada dilẹ lẹyin asunṣujẹ wọn.
 
Ọpọ igba la gbọ pe wọn ti ṣakiyesi pe awọn kan n ji Disu ti wọn n lo fi ṣiṣẹ gbe,, ṣugbọn ti wọn ko mọ awọn to wa nidii ẹ, eyi lo fa a ti wọn fi lọ bẹ awọn oṣiṣẹ So-Safe lọwẹ lati maa ba wọn ṣọ awọn ẹru wọn lalẹ, mọjumọ ọjọ keji.
 
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ naa, Mọruf Yusuf lakoko to n fi iroyin naa to wa leti sọ pe kẹẹgi ọgbọn lita mẹjọ ọtọọtọ ti wọn ti da Disu si la gbọ pe wọn gba lọwọ wọn loju ẹsẹ ti aṣiri wọn tu.
 

Iroyin fi ye wa pe wọn ti ko gbogbo lọ teṣan ọlọpaa Owode fun iṣẹ iwadii siwaju sii, gẹgẹ aṣẹ ti ọga agba pata, Sọji Ganzallo pa fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI