Irọ nla ni o, ko s'ẹni to da Zubair ati Yusuf duro lẹgbẹ oṣelu APC ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 23, 2022

Irọ nla ni o, ko s'ẹni to da Zubair ati Yusuf duro lẹgbẹ oṣelu APC ni Kwara


Ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC nipinlẹ Kwara ti f'idi awuyewuye kan to n lọ kaakiri igboro wi pe wọn ti da Ọnọrebu Kayọde Oyin Zubair ati Alaaji Fẹmi Yusuf duro ninu ẹgbẹ naa.
 
Awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa ni wọọdu Igbaja kin-in-ni, ijọba ibilẹ Ifẹlodun lo fidi iroyin naa mulẹ, ti wọn si ni irọ nla to jinna si otitọ pọnbele ni.
 
Ninu atẹjade ti awọn alakoso ẹgbẹ naa fi ọwọ si laipẹ yii ni wọn ti f'idi rẹ mulẹ pe awọn to n gbe iroyin naa kaakiri ko ni idanimọ, wọn kan fẹran lati maa da wahala silẹ laaarin ilu lasan ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI