Nitori ọmọ ọdun mẹjọ to fipa ja ibalẹ rẹ, Baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin to fẹran lati maa bawọn ọmọ kekeeke laṣepọ dero atimọle n'Ijẹbu Ode - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 24, 2022

Nitori ọmọ ọdun mẹjọ to fipa ja ibalẹ rẹ, Baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin to fẹran lati maa bawọn ọmọ kekeeke laṣepọ dero atimọle n'Ijẹbu Ode


Gẹgẹ bi orin Oloogbe Hubert Ogunde to kọ pe 'Aye, aye, aye oooo, aye d'ohun ainitunmọ o', bẹẹ gẹlẹ l'ọrọ baba arugbo, ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin kan, Stephen Jack, ti wọn lo fẹran lati maa b'awọn ọmọ kekeeke adugbo laṣepọ ri.
 
Laipẹ yii la gbọ pe ọwọ palaba Jack segi lagbegbe Okun Ọwa to wa niluu Ijẹbu, Ode, ipinlẹ Ogun.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ jẹ ko di mimọ pe ọmọ ọdun mẹjọ kan ni Jack fipa ja ibale rẹ, ko to di pe wọn lọ fi ọrọ rẹ to awọn ọlọpaa leti, ti wọn lọ gbe e lati fọrọ wa a lẹnu wo.
 
A gbọ pe kii ṣe akọkọ ree ti baba naa yoo maa b'awọn ọmọ kekeeke lagbegbe naa laṣepọ, koda, ti wọn lo gbajumọ daadaa ninu iwa yii, ṣugbọn ti wọn ni ko sẹni to le pariwo rẹ sita.
 
Eyi to ṣe pẹlu ọmọ ọdun mẹjọ naa lo mu ki ariwo rẹ gba igboro, ti onikaluku ladugbo si n sọ ohun ti mọ nipa ọkunrin naa. B'awọn kan ṣe n sọ pe ko ṣẹṣẹ maa ṣe e, bẹẹ l'awọn kan n sọ pe ori lo n ko awọn ọmọ wọn yọ.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ṣe sọ, o ni baba ọmọ ti Jack fipa ba laṣepọ lo ṣakiyesi wi pe ẹjẹ n da labẹ ọmọ rẹ, to si beere oriṣiriṣi ibeere lọwọ ẹ.

Lẹyin to ni ọmọ naa jẹwọ pe Jack lo ba oun laṣepọ, lo mu ki baba naa gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti wọn si lọ gbe e.

Oyeyẹmi fidi rẹ mulẹ pe bo tilẹ jẹ pe ọmọ naa ti wa l'ọsibitu to ti n gba itọju lọwọ, sibẹ o ni Jack ti wa ni ẹka ileeṣẹ wọn to n ri si iwadii lori ẹsun ọran

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI